إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةِ ٱلۡقَدۡرِ
Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
القدر
Read Surah Al-Qadr in Yoruba (القدر) with Arabic text, Yoruba translation, and audio recitation. Chapter 97 of the Holy Quran, 5 verses — free online.
Quran in Yoruba · all 114 Surahs
إِنَّآ أَنزَلۡنَٰهُ فِي لَيۡلَةِ ٱلۡقَدۡرِ
Dájúdájú Àwa sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú Òru Abiyì.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Isrọ̄’; 17:106.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Òru Abiyì?
لَيۡلَةُ ٱلۡقَدۡرِ خَيۡرٞ مِّنۡ أَلۡفِ شَهۡرٖ
Òru Abiyì lóore ju ẹgbẹ̀rún oṣù.
تَنَزَّلُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ فِيهَا بِإِذۡنِ رَبِّهِم مِّن كُلِّ أَمۡرٖ
Àwọn mọlāika àti Jibrīl yó sì máa sọ̀kalẹ̀ nínú òru náà pẹ̀lú àṣẹ Olúwa wọn fún gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan.
سَلَٰمٌ هِيَ حَتَّىٰ مَطۡلَعِ ٱلۡفَجۡرِ
Àlàáfíà ni òru náà títí di àsìkò àfẹ̀mọ́júmọ́.
Al-Qadr
Play