سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى
Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
الأعلى
Read Surah Al-Ala in Yoruba (الأعلى) with Arabic text, Yoruba translation, and audio recitation. Chapter 87 of the Holy Quran, 19 verses — free online.
Quran in Yoruba · all 114 Surahs
سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى
Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
ٱلَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ
Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
وَٱلَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ
Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.[1]
[1] Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa. Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn.
وَٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلۡمَرۡعَىٰ
Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,
فَجَعَلَهُۥ غُثَآءً أَحۡوَىٰ
Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.
سَنُقۡرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰٓ
Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلۡجَهۡرَ وَمَا يَخۡفَىٰ
Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.[1] Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.
[1] Ìyẹn nípasẹ̀ fífí ìdájọ́ kan pa ìdájọ́ tó ṣíwájú rẹ̀ rẹ́. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:106.
وَنُيَسِّرُكَ لِلۡيُسۡرَىٰ
Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
فَذَكِّرۡ إِن نَّفَعَتِ ٱلذِّكۡرَىٰ
Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.[1]
[1] Ìyẹn ni pé, wọ́n fẹ́ kí ṣíṣe ìrántí ọ̀rọ̀ Allāhu jìnnà sí àyè ìhunrírà (bí ilé ọtí), ilé eré àti ilé àwàdà.
سَيَذَّكَّرُ مَن يَخۡشَىٰ
Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
وَيَتَجَنَّبُهَا ٱلۡأَشۡقَى
Olórí-burúkú sì máa takété sí i.
ٱلَّذِي يَصۡلَى ٱلنَّارَ ٱلۡكُبۡرَىٰ
(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.
ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ
Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
قَدۡ أَفۡلَحَ مَن تَزَكَّىٰ
Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.[1]
[1] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:4.
وَذَكَرَ ٱسۡمَ رَبِّهِۦ فَصَلَّىٰ
Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
بَلۡ تُؤۡثِرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ
Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
إِنَّ هَٰذَا لَفِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ
Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,
صُحُفِ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ
tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.
Al-Ala
Play