أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ
Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
الشرح
Read Surah Ash-Sharh in Yoruba (الشرح) with Arabic text, Yoruba translation, and audio recitation. Chapter 94 of the Holy Quran, 8 verses — free online.
Quran in Yoruba · all 114 Surahs
أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ
Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
وَوَضَعۡنَا عَنكَ وِزۡرَكَ
A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
ٱلَّذِيٓ أَنقَضَ ظَهۡرَكَ
èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.[1]
[1] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò ṣẹbọ rí ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Allāhu, ọ̀kan nínú ohun tí ó máa ń kọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lóminú, tí ó sì máa ń bà á nínú jẹ́ ni àìdá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ àti àìní ìlànà ìjọ́sìn kan lọ́wọ́ ṣíwájú ogójì ọdún tí ó kọ́kọ́ lò.
وَرَفَعۡنَا لَكَ ذِكۡرَكَ
A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
فَإِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا
Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
إِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرٗا
Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
فَإِذَا فَرَغۡتَ فَٱنصَبۡ
Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn).
وَإِلَىٰ رَبِّكَ فَٱرۡغَب
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.
Ash-Sharh
Play