Surah An-Nas in Yoruba

    الناس

    Surah An-Nas in Yoruba

    Read Surah An-Nas in Yoruba (الناس) with Arabic text, Yoruba translation, and audio recitation. Chapter 114 of the Holy Quran, 6 verses — free online.

    Quran in Yoruba · all 114 Surahs

    1

    قُلۡ أَعُوذُ بِرَبِّ ٱلنَّاسِ

    Sọ pé: “Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn,

    2

    مَلِكِ ٱلنَّاسِ

    Ọba àwọn ènìyàn,

    3

    إِلَٰهِ ٱلنَّاسِ

    Ọlọ́hun àwọn ènìyàn,[1]

    [1] Ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun àwọn ènìyàn” ni pé, Ẹni tí àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, tí wọn kò sì gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ẹlòmíìràn lẹ́yìn Rẹ̀.

    4

    مِن شَرِّ ٱلۡوَسۡوَاسِ ٱلۡخَنَّاسِ

    níbi aburú (aṣ-Ṣaetọ̄n) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni tó bá ń dárúkọ Allāhu[1]).

    [1] Ọ̀kan pàtàkì nínú àǹfààní àti oore tí ó wà nínú ath-thikār ṣíṣe ni pé, aṣ-Ṣaetọ̄n àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóò máa sá sẹ́yìn fún ẹni tí ó bá ń ṣe ath-thikār ní gbogbo ìgbà.

    5

    ٱلَّذِي يُوَسۡوِسُ فِي صُدُورِ ٱلنَّاسِ

    (aṣ-Ṣaetọ̄n ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn.

    6

    مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ

    (Ṣaetọ̄n náà) wà nínú àwọn àlùjànnú àti àwọn ènìyàn.”

    An-Nas

    Play