Surah Al-Ikhlas in Yoruba

    الإخلاص

    Surah Al-Ikhlas in Yoruba

    Read Surah Al-Ikhlas in Yoruba (الإخلاص) with Arabic text, Yoruba translation, and audio recitation. Chapter 112 of the Holy Quran, 4 verses — free online.

    Quran in Yoruba · all 114 Surahs

    1

    قُلۡ هُوَ ٱللَّهُ أَحَدٌ

    Sọ pé: “Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.

    2

    ٱللَّهُ ٱلصَّمَدُ

    Allāhu ni Aṣíwájú tí ẹ̀dá ní bùkátà sí níbi jíjọ́sìn fún Un àti títọrọ oore ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn ní ọ̀nà kan kan.

    3

    لَمۡ يَلِدۡ وَلَمۡ يُولَدۡ

    Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.

    4

    وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ كُفُوًا أَحَدُۢ

    Kò sì sí ẹnì kan kan tí ó jọ Ọ́.”[1]

    [1] Àwọn kan máa ń ké “Ƙul huwa-llāhu” mẹ́ta fún òkú mùsùlùmí. Nígbà mìíràn, wọ́n lè ké òdidi al-Ƙur’ān fún un. Ìwọ̀nyí kò tọ sunnah rárá. Sūrah al-Haṣr; 59:10 ti fún wa ní àdúà tó jẹmọ́ òkú àti alààyè.

    Al-Ikhlas

    Play