Surah Al-Maun in Yoruba

    الماعون

    Surah Al-Maun in Yoruba

    Read Surah Al-Maun in Yoruba (الماعون) with Arabic text, Yoruba translation, and audio recitation. Chapter 107 of the Holy Quran, 7 verses — free online.

    Quran in Yoruba · all 114 Surahs

    1

    أَرَءَيۡتَ ٱلَّذِي يُكَذِّبُ بِٱلدِّينِ

    Sọ fún mi nípa ẹni tó ń pe Ọjọ́ Ẹ̀san ní irọ́!

    2

    فَذَٰلِكَ ٱلَّذِي يَدُعُّ ٱلۡيَتِيمَ

    Ìyẹn ni ẹni tó ń lé ọmọ-òrukàn dànù.

    3

    وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ

    Kò sì níí gbìyànjú láti bọ́ mẹ̀kúnnù.

    4

    فَوَيۡلٞ لِّلۡمُصَلِّينَ

    Ègbé ni fún àwọn (mùnááfìkí) tó ń kírun;[1]

    [1] Pẹ̀lú ìrun wákàtí márààrún lójoojúmọ́ ní àsìkò rẹ̀, ó ti run gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wẹẹrẹ dànù. Ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ-àforíjìn l’ó máa run àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá dànù.

    5

    ٱلَّذِينَ هُمۡ عَن صَلَاتِهِمۡ سَاهُونَ

    àwọn tó ń gbàgbé láti kírun wọn ní àsìkò rẹ̀;

    6

    ٱلَّذِينَ هُمۡ يُرَآءُونَ

    àwọn tó ń ṣe ṣekárími;

    7

    وَيَمۡنَعُونَ ٱلۡمَاعُونَ

    àti pé wọ́n ń hánnà ohun èlò (fún àwọn ènìyàn).

    Al-Maun

    Play